Home ๐ŸŽฌ Bollywood ๐ŸŽต Pakistani ๐ŸŽค English Pop

Ogun Ti Adura Oni Le Se

๐Ÿ‘ค Mega 99 โ€ข ๐ŸŽผ Prayer Point โ€ข โฑ๏ธ 8:57
๐ŸŽต 2702 characters
โฑ๏ธ 8:57 duration
๐Ÿ†” ID: 11608840

๐Ÿ“œ Lyrics

Ogun t'adura o ni le se, ma ma je o de ba mi
Aisan t'adura o ni le wo, ma ma je o de ba mi
Isoro t'adura o ni le gbo, (Oluwa) ma fi dan mi wo (o o)
Gba mi o, agbatan la ngbo'le o (Chorus ends)

(Repeat Chorus and interlude)

Opo lo ja'gun, to ja'gun b'ogun lo
Opo lo s'aisan o, to gba'be lo s'orun alakeji
Opo n'isoro de ba, t'isoro yen bori emi won
Eleda mi saanu mi o, ma je nja'gun bogun lo o o o (Repeat chorus)
Adanwo o daa rara o, adantan tun wa buru jai
Ona abayo wa o, ninu adanwo
Sugbon ko si ona abayo, ninu adantan o
Eledami gba mi o, ninu adanwo ati adantan o o o (Repeat chorus)

Oluwa! Ma je k'adura se temi ti o
Eh! Mo gbadura ko gba ma je o je temi
Ma ma je k'isoro bori emi mi o
Kori mi ma buru, k'eleda mi mo mo gbabode, Oluwa o

Eh! Adura ti o ni gba ma je o je temi
Oluwa! Gbohun mi nigba ti mba pe o o
Tori, mi o lebo ajiki mi o lebo ajisa, Oruko re ni mo ngboju le o
Wa saanu mi o

Gbohun mi, gbohun mi
Tani mo ni laiye afi're (Mi o le nikan afiwo Olorun)
Nigba t'ire ba ko mi sile
Tani yo wa gba mi
Tani yo s'amona mi (to ba ko mi sile ta lo fe gba mi?)
Ninu irin ajo mi (afi ko je imole fun okan mi)... (Repeat chorus)

Gba mi o, agbatan la ngb'ole Eze
Gba mi o, agbatan la ngb'ole o
Ogbeni nija keru o b'onija, Agb'alairara,
Agb'alaileniyan, Agb'alailoba t'o ngbani o o o
Gbami o, agbatan la ngb'ole o
Gba mi o, mi o, mi o o o o o o
Gbami o, agbatan la ngb'ole o
Mi o l'enikan afi ko gba mi l'agbatan, Olorun wa saanu aye mi i i i
Gbami o, agbatan la ngb'ole o

Tori! Bi a ba d'aso f'ole a npa laro ni
D'aso iyi bo mi Olorun
D'aso eye bo mi o
Ki asiri mi ma baa tu (tu tu tu tu)
Bi a ba d'aso f'ole a npa laro ni
D'aso iyi bo mi Olorun
D'aso eye bo mi o
Ki asiri mi ma ba tu (tu tu)... (Interlude)...

Agbatan la ngb'ole o
Mi o le da se wa gba mi i
Mo mi wo'ju re gege b'omo'kunrin ti nwowo baba re
Mo mi woju re gege b'omo'birin ti nwowo iya re re re re re re
Titi O fi saanu mi oo Olo'un
Titi O fi gbe mi ga o Olorun

Bi a ba d'aso f'ole a npa laro ni
D'aso iyi bo mi Olorun
D'aso eye bo mi o (Hey)
Ki asiri mi ma ba tu

Nitori!!! Aso Pepe ni nb'asiri Pepe
Aso ni nb'asiri ara
Eledumare Oba anjiki
Ogbamu-gbamu oju orun o se e gbamu, Oba to kari aye
Aso Pepe ni nb'asiri pepe
Aso ni nb'asiri ara
Olorun ni nbo asiri awon ayanfe re
Jo'o bo asiri mi
Olorun ni nbo asiri awon ayanfe re re re re
Jowo bo asiri mi. Bi aba oooo

Bi a ba d'aso f'ole a npa laro ni (Olorun jo'o o)
D'aso iyi bo mi Olorun (Jo'o o)
D'aso eye bo mi o (D'aso eye rere bo mi o)
Ki asiri mi ma ba tu

Oya jo! Ki asiri mi, ko bo ko ma tu o o o
Ki asiri mi ma ba tu
Loju awon to fe yeye mi,
Loju awon to fe fi mi s'eleya,
Olorun bo asiri mi o ko ma tu loju abinu eni
Ki asiri mi ma ba tu
Ki asiri mi ma ba tu

โญ Rate These Lyrics

โ˜†โ˜†โ˜†โ˜†โ˜†
Average: 0.0/5 โ€ข 0 ratings