Home 🎬 Bollywood 🎵 Pakistani 🎤 English Pop

Tuntun

👤 Oriyomi Kehinde 🎼 Ogbon ⏱️ 11:37
🎵 7049 characters
⏱️ 11:37 duration
🆔 ID: 12847542

📜 Lyrics

MashaAllah
Aole ma serawa
Iyen o ma je tuntun
Sungbon ka jaja diju

Iru e lonfa ègún
Eje ka f'oni satunse, tori ola awon omo

Aole ma serawa
Iyen o ma je tuntun
Sungbon ka jaja diju
Iru e lonfa ègún
Eje ka f'oni satunse, tori ola awon omo

Akanni mo l'alaye, feni bawu ko tetigbo o
Oro debi shàán làárìn, kama wule pé koro

Aole mo owo arawa, koma dija lojokan
Lojo toro ba dija, ko séèwò ka binu

Taba reyan da soro
E je kagba p'otilo
It's gone (Otilo)

Aole ma serawa
Iyen o ma je tuntun
Sungbon ka jaja diju
Iru e lonfa ègún
Eje ka f'oni satunse, tori ola awon omo

Setiri
Won fe iyawo lerawon
Iyen o ma je tuntun
Tiyawo tiyale nja
Ewo ni ti iya sófó
To gbenu ofofo wa

Iyale nba iyawo e ja
Iyen normal koni meaning
Ka parie funwon ni
Iyen o tun ni konma ja
Sebi tegbon taburo

Ton biwon telerawon
Sebi awon naa ma nj
Kama so'ja d'ogun ni

Aole ma serawa
Iyen o ma je tuntun
Sungbon ka jaja diju
Iru e lonfa ègún
Eje ka f'oni satunse, tori ola awon omo

Tomo tiya teba nja, kema je kija o d'ogun
Omo obàkan loba nja
Ema je koran bi ina
E yema so loju omo
Ni akoko teba nbinu

Awon omode teriyen
Won ka oro kun ju awa gan lo
Won a ni daddy loso: ka jina si egbon won
Won a ni mummy loso, kama lole aunty won

T'awon obi bawa lo tan, won a wa d'ota ara won
Eje ka f'oni satunse, tori ola awon omo ni

Aole ma serawa
Iyen o ma je tuntun
Sungbon ka jaja diju
Iru e lonfa ègún
Eje ka f'oni satunse, tori ola awon omo

Ija oni tio tan boro, loma npada di ote o, o ooh! O ooh!
Ina ote tio ba ku, loma npada di ogun

Ogun oni to pari ti, egun tirantiran ni
Isokan ni e jeawa
Kaye ma ri ija bi nkan
Tao sope koni tan mo

Alaroka nikan leyan
Timo le jina si pata
Mio ni koma soriire

Mio leni ko shanku
Taba rira ka kirawa, understanding lafiyen se

Aole ma serawa
Iyen o ma je tuntun
Sungbon ka jaja diju
Iru e lonfa ègún
Eje ka f'oni satunse, tori ola awon omo

Jerryson production
Olohun, maje kaye f'ikoro
Sinu adun toose
Karaye ma fabo mi, poko ibanuje
Toreni afe lamo, ao m'eni feni denu

Maje kaye f'ikoro
Sinu adun toose
Karaye ma fabo mi, poko ibanuje
Toreni afe lamo, ao m'eni feni denu

Anrin ao weyin, ao meni nsoni laye o
Igba tao gbin eèbù ìkà, Allah nio s'oluso wa
Aori tenikan ro, baose rise lawa nle

Eni nri ilosiwaju wa bi competition
Igba tio fimo wipe awa o ri tenikan ro
Ojo ati dale nbi toti nsogba onigba

Maje kaye f'ikoro
Sinu adun toose
Karaye ma fabo mi, poko ibanuje
Toreni afe lamo, ao m'eni feni denu

MashaAllah
Awon omo labi kale, tanro bon ose deyan nla
Lojo ririje lojo airi, anse eto wa

Nigba toba t'asiko, tafe majere omo
Olohun ma pana emi, ka gbaye jere omo

Karaso da karaso lo, katun rile fiwo
Asiko t'ounje ba rele, koma koro lailai

Maje kaye f'ikoro
Sinu adun toose
Karaye ma fabo mi, poko ibanuje
Toreni afe lamo, ao m'eni feni denu

Olopa loma nf'odaran
Tofi ngbokun lenu ise
Bi soldier sende loju ogun
Ton ngboye repete

Ika nfaye enire, fi gbokun odaju
Kiwon le ma gbinberu
Sokan awon enire
Maje kiwon tamilofa, ààbò e lemi nfe
Ati iso e timomo po nipon j'ewu irinlo

Maje kaye f'ikoro
Sinu adun toose
Karaye ma fabo mi, poko ibanuje
Toreni afe lamo, ao m'eni feni denu

Oba Olohun mi ma ma loje kin tegbe
O kamiye moma pada daun timofe da
Ibanuje ti wabigba o somi dalayo
Titi aye lope
F'olohun to lope

Oba Olohun mi ma ma loje kin tegbe
O kamiye moma pada daun timofe da
Ibanuje ti wabigba o somi dalayo
Titi aye lope
F'olohun to lope

Mo ranti ojo totipe o
Moripe opeyemi
Lojojumo lope

Titi ayeraye
Eni bamo boseri funmi
Ntipe! Tipe!! Tipe!!!

A mope ojo tipe
Tatin nfàsán denu
Kotodi powa dope, tio sebimo to dayo
Kosibi mo odire o, orin ope ma loyemi

Titi aye lope
F'olohun to lope

Oba Olohun mi ma ma loje kin tegbe
O kamiye moma pada daun timofe da
Ibanuje ti wabigba o somi dalayo
Titi aye lope
F'olohun to lope

Bee
Ojo kan nbowa, timo mo poma de
Koni bami ni saree
Ma dajo ope ma tun
Te invitation pe kewa

Kajo darin ope
Mo nbelohun ko shola
Feni towu lati wa
Tori powumi kowa

Yess iwo, mo lowumi kowa
Joko si high table mi
Titi aye lope o, fun Olohun to lope

Oba Olohun mi ma ma loje kin tegbe
O kamiye moma pada daun timofe da
Ibanuje ti wabigba o somi dalayo
Titi aye lope
F'olohun to lope

Ore, momo kinikan tipe o
Ironu o da nkan
Asiko tofi nronu

Ko sadua lomaye
Toripe eni nsunkun
O nko letter sarun ni

Ba sunkun oore made
Bao sunkun oore made
Konida koju tifo, koto dipe oore made
Konida kapa tiro

Nitori e maronu o
Iwo shama dupe
F'olohun to lope (Oya)

Oba Olohun mi ma ma loje kin tegbe
O kamiye moma pada daun timofe da
Ibanuje ti wabigba o somi dalayo
Titi aye lope
F'olohun to lope

(E pemi) l'awo akoko o
Mo sope ko (Bamise)
(Agbega) moni mofe o

Sewari potise (Mo l'olohun) to ngbope (Idera) malo funmi
Loje ki (Opeyemi)

O pada tunwa se (Oore)
Motun wa belohun pe o (Ogbon) timo fefise
Komaje ko wonmi
Kinle r'ayo mi lope o

Titi aye lope o
F'olohun to lope

Oba Olohun mi ma ma loje kin tegbe
O kamiye moma pada daun timofe da
Ibanuje ti wabigba o somi dalayo
Titi aye lope
F'olohun to lope

Interlude
Tolahal badiru alaena (alaena)
Min tseniyatil wadahi (wadahi)
Wajabal shukiru alaena (alaena)
Man daha lilahi (daahi)

Ayo wa jeko soju orewa (ore wa)
Ire wa koma seyin ota wa (ota wa)
Kalejo wobi tan o foju si (fojusi)

Awon tan o gbero kale debi a fede (ti afe de)
Kon pada woran bonse kesan iwa won (awon iwa won)

I hoped to be the winner of the battle (mo dasegun)
I later overcome all of my sorrow (mo dasegun)

Mo gbero lati segun opo ogun (i am a winner)
Mo mati bori gbogbo isoro (I am a winner)

Tolahal badiru alaena (alaena)
Min tseniyatil wadahi (wadahi)
Wajabal shukiru alaena (alaena)
Man daha lilahi (daahi)

Yah robbi mafi akisa gbeyin aso wa
Mafi egungun keyin eran wa
Mafi ibanuje keyin ayo funwa o
Mafi gangangan gbeyin opolo

Mafi akisa keyin aso wa
Mafi egungun keyin eran wa
Mafi ibanuje keyin ayo funwa o
Mafi gangangan keyin opolo

Kawon alaini pada wa lola
Làálâ kòókō won o nija s'asan
Won jiya pupo gan, je konpada wani

Tonba pada wa nitan, ma maje kotan
Ma dagba pada saida kon tesiwaju
Mafi ibanuje gbeyin ayo funwon o, mafi gangangan gbeyin opolo

Mafi akisa keyin aso wa
Mafi egungun keyin eran wa
Mafi ibanuje keyin ayo funwa o
Mafi gangangan keyin opolo

Kawon olola wa mapada toroje
Konma pada wa bewa fun owo yiya
Kawon dukia mama se parun

Anjola won kon tesiwaju
Ma mase fisoro gbeyin ola funwon o, mase fekisa gbeyin aso amin

Mafi akisa keyin aso wa
Mafi egungun keyin eran wa
Mafi ibanuje keyin ayo funwa o
Mafi gangangan keyin opolo

Naam, aduro t'olohun mi malo raye gbe
Koni jogun ofo kole se lasan
Taba nsadua ka fokan si pore ade

Tori adua longba kii s'agbara
Mapada leyin mi jowo oba rere
Koma f'aburu keyin awon ore wa

Mafi ibanuje keyin ayo funwa o
Mafi gangangan keyin opolo

Mafi akisa keyin aso wa
Mafi egungun keyin eran wa
Mafi ibanuje keyin ayo funwa o
Mafi gangangan keyin opolo

Oba tonsomi o leku (oba ni)
Taraye banku oun o leku (oba ni)
Tomo eda bante oun o le te (oba ni)

Tomo eda banku oun o leku (oba ni)
Oba tonsomi o le te (oba ni)
Oba ni (MashaAllah) (oba ni)

⭐ Rate These Lyrics

Average: 0.0/5 • 0 ratings