Home ๐ŸŽฌ Bollywood ๐ŸŽต Pakistani ๐ŸŽค English Pop

Matters Arising (Live)

๐Ÿ‘ค Beautiful Nubia, the Roots Renaissance Band โ€ข ๐ŸŽผ Live Concert Series III โ€ข โฑ๏ธ 6:39
๐ŸŽต 891 characters
โฑ๏ธ 6:39 duration
๐Ÿ†” ID: 9155932

๐Ÿ“œ Lyrics

E a ma de o, a ma de o
A wa nk'ilo fun'ra wa ni o
E a ma de o, a ma de o
E je a s'otito fun'rawa o
Iwo gb'esin s'ori, gbogbo ara ilu ti wa d'elese loju e
Eyin gbesin s'ori, e wa npa'niyan l'oruko Olorun l'oke
Se iwo ti gbagbe
P'Olorun oba, Olorun ife ni kii korira
Se eyin ti gbage p'Eledumare alagbara
O le gbe'ja ara re
Iwo de'po ola, o wa nsi'wa wu, o ti gbagbe orisun
On j'aye olowo, omode ilu nwo'nu akitan k'ebi ma pa won o
Ko le s'alaafia ninu ilu b'inu ara ilu o ba dun
Ko le s'alaafia f'olowo fun talaka
Ba o ba s'otito n'ijoba o
Ore otito s'owon o
Ife otito s'owon ye
Oo le gb'ara l'enikankan o
Won a ba e je o, won a ba e mu o
To ba y'eyin pada, won a s'oro e ni buruku
Won a ba e l'ogba, won a ba e je'gbadun
B'igba ba yi pere gbogbo won a sa lo o
Ilara ti poju, ikorira ti poju
Ko le s'ilosiwaju ninu abosi
Ikunsinu ti poju at'imoteni nikan
Ko le s'ilosiwaju ninu iwa ibaje yi o

โญ Rate These Lyrics

โ˜†โ˜†โ˜†โ˜†โ˜†
Average: 0.0/5 โ€ข 0 ratings